Ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kìíní, osù kẹfà, ọdún 2026, Rasaq Hammed, ẹnì kan tó ń lo X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi ti wọ́n ń pè ní Twitter tẹ́lẹ̀ sọ pé wọ́n ti ti ilé ẹ̀kọ́ tí a mọ̀ sí Ládòkè Akíntọ́lá University of Technology (LAUTECH) lẹ́hìn ìgbà tí àwọn ènìyàn kan sọ pé àwọn oníwà jàgídíjàgan kọlù ilé ẹ̀kọ́ yìí.
Ẹni yìí sọ̀rọ̀ yìí nígbà tí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń jẹ́ Take It Back Movement àti àwọn olùkọ́ kan ní Ìbàdàn fi ẹ̀hónú hàn nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọkandinlogoji àti àwọn olùkọ́ méje tí àwọn ajínigbé jí gbé ní ọjọ́ kẹẹdogun, osù karùn-ún, ọdún 2026 ní ilé ẹ̀kọ́ mẹ́ta ní ìjọba ìbílẹ̀ Oríire, ní Ògbómọ̀sọ́, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Nígbà ìkọlù yìí, àwọn akọluni yìí pa igbá-kejì ọ̀gá àwọn olùkọ́ àti ẹnì kan tó gun ohun agbénirìn (motorcycle) ní ilé ẹ̀kọ́ tí ó ń jẹ́ Community High School, ní Ahoro Esiele, ìkan lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọlù.
Lẹ́hìn àwọn ọjọ́ díẹ̀, àwọn ajínigbé yìí gé orí Michael Oyedokun, ìkan lára olùkọ́ tí wọ́n jí gbé, ẹni tí wọ́n dè mọ́ igi kí wọ́n tó paá.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ kí àwọn ènìyàn fi ẹ̀hónú hàn.
Ní ọjọ́ ajé yìí, àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ẹ̀hónú hàn lọ sí ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Ìbàdàn, wọ́n sọ fún ìjọba pé kí wọ́n se ọ̀nà bí wọ́n se máa gba àwọn ènìyàn tí wọ́n jí gbé yìí sílẹ̀.
Hammed sọ pé nítorí ìbẹ̀rùbojo tó ń pọ̀ sí, àwọn aláṣẹ LAUTECH ti ilé ẹ̀kọ́ yìí, wọ́n sì sọ fún àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn pé kí wọ́n wá mú àwọn ọmọ wọn.
“Wọ́n ti ti LAUTECH lónìí nítorí pé àwọn oníwà jàgídíjàgan kọlù ilé ẹ̀kọ́ yìí,” báyìí ni Hammed se sọ.
“Wọ́n gba àwọn òbí àti alágbàtọ́ ní àmọ̀ràn pé kí wọ́n lọ mú àwọn ọmọ wọn.
“Tí wọ́n bá ń bọ̀, wọn kò gbọ́dọ̀ gba Ìsẹ́yìn wọ Ògbómọ̀sọ́, kí wọ́n gba Ìbàdàn wọlé nítorí pé àwọn ajínigbé ti wà ní Ògbómọ̀sọ́.
“Ní àfikún, wọn kò gbọ́dọ̀ wọ Ògbómọ̀sọ́ ni alẹ́ tàbí òru tàbí kí ilẹ̀ tó mọ́. Ẹ jọ̀wọ́ fi ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn mìíràn. Ẹ seun. Èyí bani nínú jẹ́. Kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́.”
Lẹ́hìn ọ̀rọ̀ yìí, ó fi orúkọ Seyi Makinde, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ti ààrẹ Bọ́lá Tinubu sínú ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Mo rò pé ó yẹ kí ẹ kọ̀wé fipò yin sílẹ̀ tí ẹ kò bá lè dá ààbò bo àwọn ènìyàn mọ́.”
Àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ń lo X àti Facebook, tí a rí níbí àti níbí, pín ọ̀rọ̀ yìí, èyí tí àwọn ènìyàn tún pín lórí WhatsApp, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrọ.
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Nínú ọ̀rọ̀ kan tí àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ yìí fi síta ní ogúnjọ́, osù karùn-ún, ọdún 2026, wọ́n sọ fún gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn kí wọ́n lọ sílé fún ọ̀sẹ̀ kan láti ọjọ́ kejilelogun, osù karùn-ún, ọdún 2026 láti lọ se ọdún Iléyá (Eid-el-Kabir) pẹ̀lú àwọn òbí wọn.
Àwọn aláṣẹ yìí fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé wọn yóò padà fún ẹ̀kọ́ wọn ní ọjọ́ kìíní, osù kẹfà, ọdún 2026.
“A rọ gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n fi ọjọ́ yìí sọ́kàn, kí wọ́n sì padà sílé ẹ̀kọ́ lásìkò, nítorí pé ẹ̀kọ́ máa bẹ̀rẹ̀ láì fi àkókò ṣòfò,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí, èyí tí Olayinka Balogun, ìkan nínú àwọn ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ náà bu ọwọ́ lù se wí.
Láti ọjọ́ kẹrinlelogun, osù karùn-ún, ọdún 2026 tí ilé ẹ̀kọ́ yìí ti fi ọ̀rọ̀ yìí sórí Facebook àti X, wọn kò tíì sọ̀rọ̀ tó yí ọjọ́ tí wọ́n ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn wọlé padà.
Nígbà tí ó ń bá CableCheck Newspaper sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ àlàmísì/ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrin, osù kẹfà, ọdún 2026, Lékan Fádèyí, olórí àwọn agbẹnusọ fún LAUTECH sọ pé “irọ́ lásán-làsàn” ní ọ̀rọ̀ tí Hammed sọ. Fádèyí sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí padà sí ilé ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kìíní, osù kẹfà, ọdún 2026, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìdánwò, èyí tí wọn kò lè parí nítorí Eid-el-Kabir.
“Irọ́ gbáà ni. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa wà ní ilé ẹ̀kọ́ wa, wọ́n ti ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdánwò wọn tí wọn kò lè parí nítorí Eid-el-Kabir,” báyìí ni Fádèyí se sọ.
BÍ CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Irọ́ ni.